0 0
Read Time:1 Minute, 48 Second

Eyanmi,

E ma je ka tan ara wa je, aiye le! Eni ti o baa so wipe ko si aiye, onitohun ti ku won o ti sin ni.

Aiye lo ma pe ole ki o wa ja, won a de tun lope oloko ki o wa mu. Eni ti ko ba sora won a ti debi to lapere won a de ja ju sile nigbati isooro ba de. Eyi to buuru ju ni wipe awon ni won a tun koko bu eni naa.

A fi ki Olorun sowa.

Aiye ti won a so fun e wipe adegun, ko to seju pe won tun ti yi ohun pada wipe adeogun tun ni. Mo raiye mo beru aiye ooo.

Ta wa ni aiye ohun?

Eniyan lo n je be! Eniyan, abidi yanyan. Awon ti won ari e, won a ki e. To ba pa eyinda, won a da yeye re sile. Eyanmi, to ba gbe ara le aiye, erin re pami gan.

Ibi ti a joko si yi la ma wa ti awon meji a bere sini ti tele ara won leyin gbongbon, won a maa ni awon hun she ore kori-kosun, won a mo asiri ara won. Laipe laijino bi ija bati de, emi lero pe oni kaluku a de malo ni ilo tie ni, iro nla.

Gbogbo asiri towa laarin won a beere sini jade Sita. Gbogbo oro ti won fi pamo si ara won lowo adi ohun ti Gbogbo aiye mo. Won a wa fe ibi ara won sita lai bikita. Aiye leri yen ooo.

Yoruba 8.jpg
Photo by Tope A. Asokere on Pexels.com

Emi ri aiye mo beru ooo. Nitori eni ti aiye ba shi oju le, Oba oke nikan lo le ko onitohun yo ninu igbekun won.

Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi, Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi.

Emi ni ti re ni tooto,

Ruka

Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.

About Post Author

Ruka

My name is Ruka. Born and bred in Nigeria. Now living in Ireland. I am a Woman, Feminist, Wife, Mother, Muslim, Black, and African. I am an Entrepreneur who also works in Finance Administration. I am a Fibromyalgia & Chronic Pain Warrior. I love writing and hope to make a name for myself doing it.
Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply