0 0
Read Time:1 Minute, 38 Second

Eyanmi,

Je kin so oro kan fun e!

Nje o mo wipe awon eyan kan wa ti won a she aida tan si e, won a waa mareti ki o binu?

Won kun igbooro! Je ki nja e si. To ba fe pa won ku, iwo sebi eni pe o moo nkan ti won se. Ma bawon binu, maa ja. Saa maa wo won niran.

Nkan ti o maa dun iru won niyen. Ti o ba bawon binu, o ti fun won ni agbara niyen.

Ero okan won ni wipe ki won da gogo opolo e ru, ki o maa ni isinmi. Ki idaamu okan maa ba e ja.

She o fe fun won ni iru agbara be lori e? Eewo!

Wa ri wipe fun ra ara won ni won maa wa ka niwaju e bi aje. Nigbati Olorun oba ba fe she idajo fun won.

Iru won o ki ni isinmi nitori gbogbo ojo aiye won ote ati rikishi ni won hun ba kakiri.

Ejo elejo, oro oloro, aiye alaye niwon ma hun sho kakiri. Asiko wo wa ni won fi hun gbe igbesi aiye tiwon? Ko ye mi ooo!

Ma je ki oro won jo eloju! Fi won she aworan, fi wiwo lai soro te won lorun.

Iwo sha ti maa she rere, ma she ibaje si omo lakeji re. Ma ro ibi si enikeni. Eledumare nri gbogbo wa ati ise owo wa.

Oro no re ooo!

Mo ki gbogbo yin tayo tayo. Mo ki yin teye teye. E seun. Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi, Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi.

Emi ni ti re ni tooto,

Ruka

Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.

About Post Author

Ruka

My name is Ruka. Born and bred in Nigeria. Now living in Ireland. I am a Woman, Feminist, Wife, Mother, Muslim, Black, and African. I am an Entrepreneur who also works in Finance Administration. I am a Fibromyalgia & Chronic Pain Warrior. I love writing and hope to make a name for myself doing it.
Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply